30/09/2026
*ÀKÓJỌPỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ ỌGBỌ̀N ỌJỌ́ OṢÙ KẸSÀN-ÁN ỌDÚN 2026*
1 *ALÁṢẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ TI DÉ PADÀ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ LÁNÀÁ LẸ́YÌN Ọ̀SẸ̀ DÍẸ̀ TÓ LÒ LÁWỌN ORÍLẸ̀ ÈDÈ MÌÍRÀN*
2. *ÀLÍKÒ DÁŃGÒTÉ TI SỌ̀RỌ̀ JÁDE PÉ Ó YẸ KÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ ÁFRÍKÀ TI MÁA PÈSÈ EPO NÍBI ẸBU ÌFỌPO TI Ẹ̀ TÓ BÁ MA FI DI ỌDÚN 2030*
3. *ILÉ IṢẸ́ ỌMỌ OLÓGUN ṢÍṢỌ LÓJÚ ÀWỌN ILÉ TÓ TÓ ÀÁDỌ́TA FÚN ÌYÀWÓ ÀWỌN ỌMỌ OLÓGUN TÍ WỌ́N TI ṢUBÚ LÓJÚ ÌJÀ NÍ ÌLÚ ÌBÀDÀN*
4. *ILÉ ẸJỌ́ TI PÀṢẸ KÍ ÌGBẸ́JỌ́ KÍÁKÍÁ Ó BẸ̀RẸ̀ LÓRÍ IGBÁKEJÌ Ọ̀GÁ ỌLỌ́PÀÁ PÁTÁPÁTÁ, DCP ABBA KYARI*
5. *ÀWỌN ỌMỌ ILÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢÒFIN ÌPÍNLẸ̀ Ọ̀YỌ́ TI GBÉ ÀTÚNṢE ÀBÁDÒFIN TÓ WÀ FÚN ÌDÁSÍLẸ̀ ỌLỌ́PÀÁ ÌPÍNLẸ̀ GBA IPELE TÓ KÀN*
6. *ÌYÁBỌ̀ ỌBÁSANJỌ́ TI KÉ GBÀJARÈ SÍTA LÓRÍ ÌDÚNKOKÒ MỌ́ Ẹ̀MÍ LẸ́YÌN ÌKỌLÙ ÈTÒ ÌPOLONGO ÌBÒ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PEOPLES DEMOCRATIC PARTY (PDP) NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN*
7. *ÌJỌBA ORÍLẸ̀-ÈDÈ TURKEY TI MÚ OLÓRÍ ÀWỌN IKỌ̀ TÓ Ń DARÍ ERÉ ÌDÁRAYÁ BỌ́Ọ̀LÙ ALÁFẸSẸ̀GBÁ ÀTÀWỌN MÌÍRÀN LÓRÍ Ẹ̀SÙN LÍLU JÌBÌTÌ*
8. *ÀWỌN TÓ Ń KỌJÁ LỌ BẸ̀RẸ̀ SI NÍ MU ÀWỌN ỌTÍ TÍ ỌKỌ̀ Ẹ̀ NÍ ÌJÀM̀BÁ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ*
9. *ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ TI RỌ́WỌ́ TÓ ỌKÙNRIN KÀN LÓRÍ Ẹ̀SÙN ÌJÍNIGBÉ NÍ ÌPÍNLẸ̀ BAUCHI, BẸ́Ẹ̀ NI WỌ́N DÓÒLÀ Ẹ̀MÍ ỌMỌ TÍ Ó JÍ GBÉ NÁÀ*
10. *ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ ALLIED PEOPLES MOVEMENT (APM) TI RỌ ILÉ ÌFOWÓPAMỌ́ ÀGBÁYÉ LÁTI KỌ ÌBÉÈRÈ ALÁṢẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ LÓRÍ ÌGBÉSẸ̀ Ẹ̀ LÁTI YÁ OWÓ TÓ TÓ BÍLÍỌ̀NÙ KAN ÀTÀBỌ̀ OWÓ ILẸ̀ ÒKÈÈRÈ ( #1.5bn)*
11. *ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PEOPLES DEMOCRATIC PARTY (PDP) TI SỌ̀RỌ̀ JÁDE PÉ IRỌ́ ŃLÁ TÓ JÌNNÀ SÍ ÒTÍTỌ́ NI ÌRÒYÌN KAN TÓ Ń JÀ RÀN-ÌN RÀN-ÌN KIRI PÉ WỌ́N TI YỌ HON. ỌLÁDIPÚPỌ̀ ADÉBUTÚ KÚRÒ NÍNÚ ÀWỌN OLÙDÍJEDUPÒ GÓMÌNÀ BẸ́Ẹ̀ NI WỌ́N WÁ SỌ PÉ KÍ YÁYÌ WÁ JÚWE IBI TÍ WỌ́N TI BI NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN*
12. *ILÉ ẸJỌ̀ TI PÀṢẸ GBÍGBA GBOGBO Ẹ̀RỌ ÌBANISỌ̀RỌ̀ IRINWÓ ÀTI MỌ́KÀNLÉLỌ́GBỌ̀N (431) TÍ WỌ́N GBÀ LỌ́WỌ́ AFURASÍ ỌMỌ ORÍLẸ̀-ÈDÈ CHINA NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ*
13. *GÓMÌNÀ OKPEBHOLO TI JẸ́ KÓ DI MÍMỌ̀ PÉ ÀTI ÌGBÀ TÍ ÒUN TI WÀ NÍ ỌMỌ ỌDÚN MẸ́TÀDÍNLÓGÚN NI ÒUN TI Ń LÉ Ẹ̀MÍ ÈṢÙ JÁDE*
14. *ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ ALL PROGRESSIVES CONGRESS (APC) NÍ ÌPÍNLẸ̀ ÒGÙN GBÉ ÀDÚRÀ ÀWỌN ẸLẸ́SÌNJẸSÌN SÍLẸ̀ FÚN ÌJAWÉ OLÚBORÍ ALÁṢẸ BỌ́LÁ TINÚBÚ, ỌLÁMILÉKAN ADÉỌLÁ YÁYÌ, DÀPỌ̀ ABÍỌ́DÚN ÀTÀWỌN MÌÍRÀN*
15. *ÀLÍKÒ DÁŃGÒTÉ TI ṢÈLÉRÍ LÁTI DÁ ÀÀBÒ BO IṢẸ́ ÀKÀNṢE ẸBU ÌFỌPO KENYA LỌ́WỌ́ ÀWỌN ONÍ WÀHÁLÀ*
*OLÚWATÓBILỌ́BA DÁRAMỌ́LÁ (GLAMOURLADY)*
*LÓ Ń JÁBỌ̀ ÌRÒYÌN ÒWÚRỌ̀ ÒNÍ FÚN ÌKÀNNÌ AMÓHÙNMÁWÒRÁN YORÙBÁ BROADCASTING NETWORK (YBN)*